3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òun ẹ̀tàn;wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;
4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkànígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára:wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹ,ìwọ Olúwa,ó ga dé ọ̀run,òtítọ́ ọ̀ Rẹ ga dé àwọ̀sánmà.
6 Òdodo Rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,àwọn ìdájọ́ Rẹ dàbí ibú ńlá;ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
7 Báwo ni ìṣeun ìdúróṣinṣin ìfẹ́ Rẹ ti tó!Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn lesá sí abẹ́ òjijì ìyẹ́ Rẹ.
8 Àsè ilé Rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùngidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn munínú odò inú-dídùn Rẹ.
9 Nítorí pé pẹ̀lú ù Rẹ ni orísun ìyè wà:nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.