1 Àti fi ètí wa gbọ́, Ọlọ́runàwọn baba wa tí sọ fún waoun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
2 Ìwọ fi ọwọ́ Rẹ̀ lé orílẹ̀-èdè jádeÌwọ sì gbin àwọn baba wa;Ìwọ run àwọn ènìyàn náàÌwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
3 Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọn gba ilẹ̀ náà,bẹ́ẹ̀ ni kì í se apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò se;ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ àti, apá Rẹ̀;àti ìmọ́lẹ̀ ojú Rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.
4 Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jákọ́bù.
5 Nípaṣẹ̀ Rẹ̀ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣúbú; nípasẹ̀ orúkọ Rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá ti ó dìde sí wa mọ́lẹ̀
6 Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun miidà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,