14 Ṣùgbọ́n ní tèmí, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sì i.
15 Ẹnu mí yóò sọ nípa ti òdodo Rẹ,ti ìgbàlà Rẹ ni gbogbo ọjọ́lóòtọ́, èmi kò mọ́ iye Rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára Olúwa Ọlọ́run;èmi ó kéde òdodo Rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ tí kọ́ mítítí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí ẹnu di arúgbó tán tí mo sì hewú,Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́runtítí tí èmi o fi ipá re han ìran yìíàti agbára Rẹ fún gbogbo àwọn aráẹ̀yìn, sọ ti agbára sí ìran tí ń bọ̀agbára Rẹ̀ fún àwọn tí yóò wá.
19 Ọlọ́run, Òdodo Rẹ̀ dé ọ̀run,ìwọ tí ó ti ṣe ohun ńláTa ni, Ọlọ́run, tí o dà bí i Rẹ?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí o pọ̀ tí ó sì korò,ìwọ yóò tún sọ ayé mi jíìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókèláti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀