4 Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́runpẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.
5 Èéṣe tí o fi n rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?Èéṣe tí ara Rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?Ìwọ ṣe ìrètí ni ti Ọlọ́run,nítorí èmi yóò sáà máa yìn ín.
6 Olùgbàlà mi àtiỌlọ́run mi,ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:nítorí náà, èmi ó rántí Rẹláti ilẹ̀ Jọ́dánì wá,láti Hámónì láti òkè Mísárì.
7 Ibú omi ń pe ibú ominípa híhó omi ṣíṣàn Rẹ̀gbogbo rírú omi àti bíbì omi Rẹ̀bò mí mọ́lẹ̀.
8 Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ Rẹ̀,àti ni àṣálẹ́ ni orin Rẹ̀ wà pẹ̀lú miàdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.
9 Èmi wí fún Ọlọ́run àpátà mi,“Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,nítorí ìnilára ọ̀ta?”
10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tíàwọn ọ̀ta mi ń gàn mí,Bí wọn ti ń béèrè ni gbogbo ọjọ́.“Níbo ni Ọlọ́run Rẹ wà?”